KRONIKA KEJI 1:1-17

KRONIKA KEJI 1:1-17 YCE

Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá. Solomoni bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀: àwọn balogun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn adájọ́, àwọn olórí ní Israẹli ati àwọn baálé baálé. Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀. Ṣugbọn Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá láti Kiriati Jearimu sinu àgọ́ tí ó pa fún un ní Jerusalẹmu. Pẹpẹ bàbà tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri ṣe, wà níbẹ̀ níwájú àgọ́ OLUWA. Solomoni ati àwọn eniyan rẹ̀ sin OLUWA níbẹ̀. Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.” Solomoni dá Ọlọrun lóhùn, ó ní “O ti fi ìfẹ́ ńlá tí kìí yẹ̀ han Dafidi, baba mi, o sì ti fi mí jọba nípò rẹ̀. OLUWA, Ọlọrun, mú ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ nisinsinyii, nítorí pé o ti fi mí jọba lórí àwọn eniyan tí wọ́n pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. Fún mi ní ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí n óo fi máa ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi, nítorí pé ó ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ tó báyìí.” Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí, n óo fún ọ ní ọgbọ́n ati ìmọ̀; n óo sì fún ọ ní ọrọ̀, nǹkan ìní, ati ọlá, irú èyí tí ọba kankan ninu àwọn tí wọ́n ti jẹ ṣiwaju rẹ kò tíì ní rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí èyí tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ tí yóo ní irú rẹ̀.” Solomoni kúrò ní àgọ́ ìpàdé tí ó wà ní ibi ìrúbọ ní Gibeoni, ó wá sí Jerusalẹmu, ó sì jọba lórí Israẹli. Solomoni kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin jọ; àwọn kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ egbeje (1,400) àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ ẹgbaafa (12,000); ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Fadaka ati wúrà tí ọba kójọ, pọ̀ bíi òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bí igi sikamore tí ó wà ní Ṣefela, ní ẹsẹ̀ òkè Juda. Láti Ijipti ati Kue ni Solomoni ti ń kó ẹṣin wá, àwọn oníṣòwò tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún un ni wọ́n ń ra àwọn ẹṣin náà wá láti Kue. Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria.