TIMOTI KINNI 2:1-4

TIMOTI KINNI 2:1-4 YCE

Nítorí náà, lákọ̀ọ́kọ́, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o máa tọrọ ninu adura, kí o máa bẹ̀bẹ̀, kí o sì máa dúpẹ́ fún gbogbo eniyan, fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí. Irú adura báyìí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun Olùgbàlà wa, ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú TIMOTI KINNI 2:1-4