TẸSALONIKA KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Tẹsalonika ni olú-ìlú ìpínlẹ̀ Masedonia tí ó wà ní abẹ́ ìjọba Romu. Paulu dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́yìn tí ó kúrò ní Filipi. Ṣugbọn kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà tí àwọn Juu kan fi bẹ̀rẹ̀ sí tako Paulu, nítorí pé wọ́n ń jowú rẹ̀ pé ó ṣe àṣeyege; nítorí pé ó waasu nípa ẹ̀sìn igbagbọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu, ṣugbọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí ẹ̀sìn àwọn Juu. Túlààsì ni Paulu fi kúrò ní Tẹsalonika tí ó sì lọ sí Beria. Nígbà tí ó yá, tí ó dé Kọrinti, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ kan tí ń jẹ́ Timoti fún un ní ìròyìn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Tẹsalonika.
Ní àkókò yìí ni Paulu kọ ìwé rẹ̀ kinni sí àwọn ará Tẹsalonika. Ó kọ ọ́ láti mú àwọn onigbagbọ tí wọ́n wà níbẹ̀ lọ́kàn le ati láti fún wọn ní ìdánilójú. Ó dúpẹ́ fún ìròyìn tí ó gbọ́ nípa ìfẹ́ ati igbagbọ wọn, ó sì rán wọn létí irú ìgbé-ayé tí ó gbé nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bèèrè láàrin ìjọ nípa ìpadàbọ̀ Kristi. Díẹ̀ ninu àwọn ìbéèrè náà nìwọ̀nyí: Bí onigbagbọ kan bá jáde láyé kí Kristi tó pada dé, ǹjẹ́ ó ní ìpín ninu ìyè ainipẹkun tí Kristi yóo mú bọ̀ nígbà tí ó bá pada dé? Ati pé nígbà wo gan-an ni Kristi yóo pada wá? Paulu lo anfaani àwọn ìbéèrè wọnyi láti bẹ̀ wọ́n pé kí wọn máa ṣe iṣẹ́ igbagbọ wọn lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, bí wọn ti ń fi ìrètí dúró de àkókò tí Kristi ń pada bọ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1
Ìdúpẹ́ ati ìyìn 1:2–3:13
Ẹ̀bẹ̀ fún ìgbé-ayé onigbagbọ 4:1-12
Ẹ̀kọ́ nípa ìpadàbọ̀ Kristi 4:13–5:11
Ọ̀rọ̀ ìyànjú 5:12-22
Ọ̀rọ̀ ìparí 5:23-28
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
TẸSALONIKA KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010