Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín. Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn. Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii. Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin. Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú. Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn. Ẹni tí ó pè yín yóo ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé olóòótọ́ ni.
Kà TẸSALONIKA KINNI 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: TẸSALONIKA KINNI 5:15-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò