Ẹ̀yin ará, ní ìparí ọ̀rọ̀ mi, a fi Jesu Oluwa bẹ̀ yín, a sì rọ̀ yín pé gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ wa ní ọ̀nà tí ó yẹ, kí ẹ máa rìn bí ó ti wu Ọlọrun. Bí ẹ ti ń ṣe ni kí ẹ túbọ̀ máa ṣe. Nítorí ẹ mọ àwọn ìlànà tí a fun yín, nípa àṣẹ Oluwa Jesu. Nítorí ìfẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́: ẹ jìnnà sí àgbèrè. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mọ ọ̀nà láti máa bá aya rẹ̀ gbé pọ̀ pẹlu ìwà mímọ́ ati iyì, kì í ṣe pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara bíi ti àwọn abọ̀rìṣà tí kò mọ Ọlọrun. Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ̀, tabi kí ó ṣẹ arakunrin rẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Nítorí ẹlẹ́san ni Oluwa ninu àwọn ọ̀ràn wọnyi, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, tí a wá tún ń kìlọ̀ fun yín nisinsinyii. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sí ìwà èérí bíkòṣe ìwà mímọ́. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kọ ọ̀rọ̀ yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ eniyan ni ó kọ̀ bíkòṣe Ọlọrun tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fun yín.
Kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, nítorí Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti fẹ́ràn ọmọnikeji yín. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ sì ń ṣe sí gbogbo àwọn onigbagbọ ní gbogbo Masedonia. Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín, ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ati jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ gbìyànjú láti fi ọkàn yín balẹ̀. Ẹ má máa yọjú sí nǹkan oní-ǹkan. Ẹ tẹpá mọ́ṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín. Ẹ máa rìn bí ó ti yẹ láàrin àwọn alaigbagbọ, kí ó má sí pé ẹ nílò ati gba ohunkohun lọ́wọ́ wọn.
Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ má ní òye nípa àwọn tí wọ́n ti sùn, kí ẹ má baà banújẹ́ bí àwọn tí kò nírètí. Nítorí bí a bá gbàgbọ́ pé Jesu kú, ó sì jinde, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọrun yóo mú àwọn tí wọ́n ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀.
Nítorí à ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fun yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oluwa, pé àwa tí a bá wà láàyè, tí a bá kù lẹ́yìn nígbà tí Oluwa bá farahàn, kò ní ṣiwaju àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde. A óo wá gbé àwa tí ó kù lẹ́yìn, tí a wà láàyè, lọ pẹlu wọn ninu awọsanma, láti lọ pàdé Oluwa ní òfuurufú, a óo sì máa wà lọ́dọ̀ Oluwa laelae. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu.