TẸSALONIKA KINNI 2:11-13

TẸSALONIKA KINNI 2:11-13 YCE

gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé bí baba ti rí sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni a rí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín; tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀. Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.