SAMUẸLI KINNI 3

3
OLUWA Fara Han Samuẹli
1Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́. 2Ní àkókò yìí, ojú Eli ti di bàìbàì, kò ríran dáradára mọ́. Òun sùn sinu yàrá tirẹ̀, 3ṣugbọn Samuẹli sùn ninu ilé OLUWA, níbi tí àpótí Ọlọrun wà. Iná fìtílà ibi mímọ́ kò tíì jó tán. 4OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.” 5Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”
Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn.
6OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.” 7Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí.
8OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”
Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà. 9Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn.
10OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!”
Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.”
11OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu. 12Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. 13Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun. 14Nítorí náà, mo ti búra fún ilé Eli pé, kò sí ẹbọ kan tabi ọrẹ tí ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú náà kúrò laelae.”
15Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli. 16Eli pè é, ó ní, “Samuẹli, ọmọ mi!”
Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”
17Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.” 18Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.”
19Samuẹli sì ń dàgbà, OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ. 20Gbogbo Israẹli láti Dani dé Beeriṣeba, ni wọ́n mọ̀ pé wolii OLUWA ni Samuẹli nítòótọ́. 21OLUWA tún fi ara hàn ní Ṣilo, nítorí pé níbẹ̀ ni ó ti kọ́ fi ara han Samuẹli, tí ó sì bá a sọ̀rọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa