Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí. OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà. Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn. OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.”
Kà SAMUẸLI KINNI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: SAMUẸLI KINNI 3:7-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò