OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”
Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn.
OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.” Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí.
OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”
Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà. Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn.
OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!”
Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.”
OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu.