SAMUẸLI KINNI 25
25
Ikú Samuẹli
1Nígbà tí Samuẹli kú, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kó ara wọn jọ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ ní Rama.
Dafidi ati Abigaili
Lẹ́yìn náà, Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Parani. 2Ọkunrin kan wà ní ìlú Maoni tí ń ṣe òwò ní Kamẹli. Ọkunrin náà ní ọrọ̀ lọpọlọpọ; ó ní ẹgbẹẹdogun aguntan (3,000) ati ẹgbẹrun (1,000) ewúrẹ́, Kamẹli níí ti máa ń gé irun aguntan rẹ̀. 3Orúkọ ọkunrin náà ni Nabali, iyawo rẹ̀ sì ń jẹ́ Abigaili. Obinrin náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati arẹwà, ṣugbọn ọkọ rẹ̀ jẹ́ òǹrorò ati eniyan burúkú. Ìdílé Kalebu ni ìdílé rẹ̀.
4Dafidi gbọ́ ninu aṣálẹ̀ pé Nabali ń gé irun aguntan rẹ̀, 5ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun. 6Ó ní kí wọ́n kí i báyìí pé, “Alaafia fún ọ, ati fún ilé rẹ ati fún gbogbo ohun tí o ní. 7Mo gbọ́ pé ò ń gé irun àwọn aguntan rẹ, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ aguntan rẹ wà lọ́dọ̀ wa fún ìgbà pípẹ́, n kò sì ṣe wọ́n ní ibi kankan. Kò sí ohun tí ó jẹ́ tiwọn tí ó sọnù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní Kamẹli. 8Bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọdọmọkunrin rẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ. Ọjọ́ ọdún ni ọjọ́ òní, nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọmọkunrin yìí rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ mú ohunkohun tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó rẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, ati fún èmi Dafidi, ọmọ rẹ.”
9Nígbà tí àwọn tí Dafidi rán dé ibẹ̀, wọ́n jíṣẹ́ fún Nabali, ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì dúró. 10Nabali dá àwọn iranṣẹ náà lóhùn pé, “Ta ni Dafidi? Ta ni ọmọ Jese? Ọpọlọpọ iranṣẹ ni ó wà nisinsinyii tí wọn ń sá kúrò ní ọ̀dọ̀ oluwa wọn. 11Ṣé kí n wá mú oúnjẹ mi ati omi mi ati ẹran tí mo pa fún àwọn tí wọn ń gé irun aguntan mi, kí n sì gbé e fún àwọn tí n kò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”
12Àwọn ọdọmọkunrin náà bá pada lọ sọ gbogbo ohun tí Nabali sọ fún wọn fún Dafidi. 13Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.
14Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Nabali sọ fún Abigaili, iyawo Nabali pé, “Dafidi rán àwọn iranṣẹ láti aṣálẹ̀ wá sọ́dọ̀ oluwa wa, ṣugbọn ó kanra mọ́ wọn. 15Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọkunrin náà tọ́jú wa, wọn kò sì ṣe ibi kankan sí wa, nǹkankan tí ó jẹ́ tiwa kò sì sọnù nígbà tí a wà pẹlu wọn ní oko. 16Wọ́n dáàbò bò wá tọ̀sán tòru, ní gbogbo ìgbà tí a wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú agbo ẹran wa. 17Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.”
18Abigaili bá yára mú igba (200) burẹdi ati ìgò ọtí waini meji ati aguntan marun-un tí wọ́n ti sè ati òṣùnwọ̀n ọkà yíyan marun-un ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbígbẹ ati igba (200) àkàrà tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ dín, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 19Ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa lọ ṣiwaju, èmi náà ń bọ̀ lẹ́yìn,” ṣugbọn kò sọ fún ọkọ rẹ̀.
20Bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, tí ó dé abẹ́ òkè kan, ó rí i tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń bọ̀ níwájú. 21Dafidi ti wí pé, “Ṣé lásán ni mo dáàbò bo agbo ẹran Nabali ninu aṣálẹ̀, tí kò sí ohun ìní rẹ̀ kan tí ó sọnù. Ṣé bí ó ti yẹ kí ó fi ibi san ire fún mi nìyí. 22Kí Ọlọrun pa mí bí mo bá fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ láìpa ninu àwọn eniyan Nabali títí di òwúrọ̀ ọ̀la.”
23Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó sọ̀kalẹ̀ kíákíá, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá 24ẹsẹ̀ Dafidi, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, gbọ́ ti èmi iranṣẹbinrin rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ru ẹ̀bi àṣìṣe Nabali. 25Jọ̀wọ́ má ṣe ka aláìmòye yìí sí, nítorí Nabali ni orúkọ rẹ̀, bí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwà rẹ̀ rí. Oluwa mi, n kò rí àwọn iranṣẹ rẹ nígbà tí wọ́n wá. 26OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali. 27Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí èmi iranṣẹbinrin rẹ mú wá fún ọ kí o sì fi fún àwọn ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé ọ. 28Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 29Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun. 30Nígbà tí OLUWA bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tí ó sì fi ọ́ jọba ní Israẹli, 31o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.”
32Dafidi dáhùn pé, “Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó rán ọ sí mi lónìí. 33Ibukun ni fún ọ, fún ọgbọ́n tí o lò ati ohun tí o ṣe lónìí, tí o fà mí sẹ́yìn kúrò ninu ìpànìyàn ati ìgbẹ̀san. 34OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.” 35Dafidi gba ẹ̀bùn tí ó mú wá, ó sì sọ fún un pé, “Máa lọ sílé ní alaafia, kí o má sì ṣe bẹ̀rù, n óo ṣe ohun tí o sọ.”
36Nígbà tí Abigaili pada dé ilé ó bá Nabali ninu àsè bí ọba. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó ti mu ọtí ní àmupara. Abigaili kò sì sọ nǹkankan fún un títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. 37Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀ tán; Abigaili sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. 38Ní ọjọ́ kẹwaa lẹ́yìn náà, OLUWA pa Nabali.
39Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.”
Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ. 40Àwọn iranṣẹ Dafidi lọ sọ́dọ̀ Abigaili ní Kamẹli, wọ́n ní, “Dafidi ní kí á mú ọ wá, kí o lè jẹ́ aya òun.”
41Abigaili bá wólẹ̀ ó ní, “Iranṣẹ Dafidi ni mí, mo sì ti ṣetán láti ṣan ẹsẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀.” 42Ó yára gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun pẹlu àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun-un, wọ́n sì tẹ̀lé àwọn iranṣẹ Dafidi lọ, Abigaili sì di aya Dafidi.
43Dafidi ti fẹ́ Ahinoamu ará Jesireeli, ó sì tún fẹ́ Abigaili pẹlu. 44Ṣugbọn Saulu ti mú Mikali, ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ iyawo Dafidi, ó ti fún Paliti ọmọ Laiṣi tí ó wá láti Galimu pé kí ó fi ṣe aya.#2Sam 3:14-16
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KINNI 25: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010