Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.” Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.” Lẹ́yìn náà Jese sọ fún Ṣama pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli tún ní, “OLUWA kò yan eléyìí náà.” Jese mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeje kọjá níwájú Samuẹli. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, OLUWA kò yan ọ̀kankan ninu wọn. Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?” Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.” Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.” Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.”
Kà SAMUẸLI KINNI 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: SAMUẸLI KINNI 16:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò