SAMUẸLI KINNI 11
11
Saulu Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni
1Nahaṣi, ọba Amoni, kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Jabeṣi Gileadi. Àwọn ará Jabeṣi bá sọ fún Nahaṣi pé, “Jẹ́ kí á jọ dá majẹmu, a óo sì máa sìn ọ́.”
2Nahaṣi dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo fi lè ba yín dá majẹmu ni pé, kí n yọ ojú ọ̀tún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, kí ó lè jẹ́ ìtìjú fún gbogbo Israẹli.”
3Àwọn àgbààgbà Jabeṣi dáhùn pé, “Fún wa ní ọjọ́ meje, kí á lè ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Bí kò bá sí ẹni tí yóo gbà wá, a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ.”
4Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà dé Gibea, níbi tí Saulu ń gbé, wọ́n ròyìn fún àwọn ará ìlú náà, gbogbo wọn sì pohùnréré ẹkún. 5Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un. 6Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi. 7Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.”
Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan. 8Saulu bá kó wọn jọ ní Beseki. Ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ni àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n wá láti Juda sì jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000). 9Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi. 10Wọ́n wí fún Nahaṣi pé, “Lọ́la ni a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ, ohunkohun tí ó bá sì wù ọ́ ni o lè fi wá ṣe.”
11Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Saulu pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ọ̀nà mẹta, wọ́n kọlu ibùdó àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n títí di ọ̀sán ọjọ́ náà. Àwọn tí kò kú lára wọn fọ́nká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí eniyan meji tí wọ́n dúró papọ̀.
12Àwọn ọmọ Israẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Samuẹli pé, “Níbo ni àwọn tí wọ́n sọ pé kò yẹ kí Saulu jẹ ọba wa wà? Ẹ kó wọn jáde, kí á pa wọ́n.”
13Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.” 14Samuẹli wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Giligali, kí á lè túbọ̀ fi ìdí ìjọba Saulu múlẹ̀.” 15Gbogbo wọn bá pada lọ sí Giligali, wọ́n sì fi Saulu jọba níwájú OLUWA. Wọ́n rú ẹbọ alaafia, Saulu ati àwọn ọmọ Israẹli sì jọ ṣe àjọyọ̀ ńlá.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KINNI 11: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010