PETERU KINNI 5:1-6

PETERU KINNI 5:1-6 YCE

Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá. Ẹ má ṣe é bí ẹni tí ó fẹ́ jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ yín ṣugbọn ẹ ṣe é bí àpẹẹrẹ fún ìjọ. Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá. Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.” Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀.