Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní. Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ. Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.
Kà PETERU KINNI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: PETERU KINNI 3:14-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò