ÀWỌN ỌBA KINNI 18:36-39

ÀWỌN ỌBA KINNI 18:36-39 YCE

Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni. Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.” OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!”