Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa. Kí á má dàbí Kaini tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arakunrin rẹ̀. Kí ló dé tí ó fi pa á? Nítorí iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣugbọn ti arakunrin rẹ̀ dára. Ẹ má jẹ́ kí ẹnu yà yín bí ayé bá kórìíra yín. Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú. Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́. Ọ̀nà tí a óo fi mọ̀ pé a jẹ́ ẹni òtítọ́ nìyí; níwájú Ọlọrun pàápàá ọkàn wa yóo balẹ̀. Bí ọkàn wa bá tilẹ̀ dá wa lẹ́bi, kí á ranti pé Ọlọrun tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní ìgboyà níwájú Ọlọrun. À ń rí ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà, nítorí pé à ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Àṣẹ rẹ̀ nìyí: pé kí á gba orúkọ Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi, gbọ́, kí á sì fẹ́ràn ẹnìkejì wa, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi àṣẹ fún wa. Ẹni tí ó bá ń pa òfin Ọlọrun mọ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé Ọlọrun ń gbé inú wa ni nípa Ẹ̀mí tí ó ti fi fún wa.
Kà JOHANU KINNI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU KINNI 3:11-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò