Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo. Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu. Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀. Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé.
Kà JOHANU KINNI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU KINNI 2:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò