KỌRINTI KINNI 15:56-58

KỌRINTI KINNI 15:56-58 YCE

Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán.