KỌRINTI KINNI 12:18-21

KỌRINTI KINNI 12:18-21 YCE

Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà? Bí ó ti wà yìí, ẹ̀yà pupọ ni ó ní, ṣugbọn ara kan ṣoṣo ni. Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.”