KỌRINTI KINNI 1:20-30

KỌRINTI KINNI 1:20-30 YCE

Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀! Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kì í ṣe ipasẹ̀ gbogbo ọgbọ́n ayé yìí ni eniyan yóo fi mọ Ọlọrun, ó wu Ọlọrun láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa iwaasu tí à ń wà, tí ó dàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀. Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n; ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun. Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá. Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára; bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè.