KRONIKA KINNI 3
3
Àwọn Ọmọ Dafidi Ọba
1Àwọn ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Heburoni nìwọ̀nyí, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Aminoni tí Ahinoamu ará Jesireeli bí fún un ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Daniẹli, ọmọ Abigaili ará Kamẹli. 2Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọbinrin Talimai, ọba ìlú Geṣuri; lẹ́yìn náà Adonija ọmọ Hagiti. 3Ẹkarun-un ni Ṣefataya, ọmọ Abitali; lẹ́yìn rẹ̀ ni Itireamu ọmọ Egila. 4Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un.
Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn.#2Sam 5:4-5; 1A. Ọba 2:11; 1Kron 29:27
5Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:
Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni.#2Sam 11:3
6Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; 7Noga, Nefegi, ati Jafia, 8Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti, 9Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.
Ìran Solomoni Ọba
10Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati; 11Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi; 12Amasaya, Asaraya, ati Jotamu; 13Ahasi, Hesekaya, ati Manase, 14Amoni ati Josaya. 15Orúkọ àwọn ọmọ Josaya mẹrẹẹrin, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn ni: Johanani, Jehoiakimu, Sedekaya ati Ṣalumu. 16Jehoiakimu bí ọmọ meji: Jekonaya ati Sedekaya.
Àwọn Ìran Jehoiakini
17Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli, 18Malikiramu, Pedaaya, ati Ṣenasari, Jekamaya, Hoṣama ati Nedabaya. 19Pedaaya bí ọmọ meji: Serubabeli, ati Ṣimei. Serubabeli bí ọmọ meji: Meṣulamu ati Hananaya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣelomiti. 20Serubabeli tún bí ọmọ marun-un mìíràn: Haṣuba, Oheli, ati Berekaya; Hasadaya ati Juṣabi Hesedi.
21Hananaya bí ọmọ meji: Pelataya ati Jeṣaaya, àwọn ọmọ Refaaya, ati ti Arinoni, ati ti Ọbadaya, ati ti Ṣekanaya. 22Ṣekanaya ní ọmọ kan, tí ń jẹ́ Ṣemaaya. Ṣemaaya bí ọmọ marun-un: Hatuṣi, Igali, Baraya, Nearaya ati Ṣafati. 23Nearaya bí ọmọ mẹta: Elioenai, Hisikaya ati Asirikamu. 24Elioenai bí ọmọ meje: Hodafaya, Eliaṣibu, Pelaaya, Akubu, Johanani, Delaaya ati Anani.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010