KRONIKA KINNI 21
21
Dafidi Ṣe Ètò Ìkànìyàn
1Satani fẹ́ ta jamba fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí náà ó gbó Dafidi láyà láti kà wọ́n. 2Dafidi sọ fún Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé, “Ẹ lọ ka àwọn ọmọ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, kí ẹ wá fún mi lábọ̀, kí n lè mọ iye wọn.”
3Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?” 4Ṣugbọn ti ọba ni ó ṣẹ, Joabu bá lọ kà wọ́n jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì pada wá sí Jerusalẹmu. 5Joabu fún ọba ní iye àwọn ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ marundinlọgọta (1,100,000) ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, ati ọ̀kẹ́ mẹtalelogun ó lé ẹgbaarun (470,000) ninu àwọn ẹ̀yà Juda. 6Nítorí pé àṣẹ tí ọba pa yìí burú lójú Joabu, kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi ati ti Bẹnjamini.
7Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà. 8Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, níti ohun tí mo ṣe yìí. Mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ji èmi iranṣẹ rẹ, nítorí pé ìwà òmùgọ̀ ni mo hù.”
9Ọlọrun bá rán Gadi, aríran Dafidi pé, 10“Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ”
11Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi: 12yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”
13Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”
14Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan. 15Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.
16Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀. 17Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.”
18Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi. 19Dafidi bá dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, tí ó sọ ní orúkọ OLÚWA. 20Onani ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mẹrin wà níbi tí wọ́n ti ń pakà. Nígbà tí wọ́n rí angẹli náà, wọ́n sápamọ́. 21Bí Dafidi ti dé ọ̀dọ̀ Onani, tí Onani rí i, ó kúrò níbi tí ó ti ń pa ọkà, ó lọ tẹríba fún Dafidi, ó dojúbolẹ̀. 22Dafidi sọ fún un pé, “Ta ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA. Iye tí ó bá tó gan-an ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”
23Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”
24Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.” 25Nítorí náà, Dafidi fún Onani ní ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli wúrà, fún ilẹ̀ ìpakà náà. 26Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.
27OLUWA pàṣẹ fún angẹli náà pé kí ó ti idà rẹ̀ bọ inú àkọ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 28Nígbà tí Dafidi rí i pé OLUWA ti gbọ́ adura rẹ̀ ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ rẹ̀ níbẹ̀. 29Títí di àkókò yìí, àgọ́ OLUWA tí Mose pa ní aṣálẹ̀, ati pẹpẹ ẹbọ sísun wà ní ibi pẹpẹ ìrúbọ ní Gibeoni. 30Ṣugbọn Dafidi kò lè lọ sibẹ láti wádìí lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí ó ń bẹ̀rù idà angẹli OLUWA.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 21: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010