1
Filipi 4:6
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Filipi 4:6
2
Filipi 4:7
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.
Ṣàwárí Filipi 4:7
3
Filipi 4:8
Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.
Ṣàwárí Filipi 4:8
4
Filipi 4:13
Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.
Ṣàwárí Filipi 4:13
5
Filipi 4:4
Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.
Ṣàwárí Filipi 4:4
6
Filipi 4:19
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.
Ṣàwárí Filipi 4:19
7
Filipi 4:9
Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.
Ṣàwárí Filipi 4:9
8
Filipi 4:5
Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí.
Ṣàwárí Filipi 4:5
9
Filipi 4:12
Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní.
Ṣàwárí Filipi 4:12
10
Filipi 4:11
Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀.
Ṣàwárí Filipi 4:11
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò