1
Lefitiku 19:18
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni OLúWA.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Lefitiku 19:18
2
Lefitiku 19:28
“ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni OLúWA.
Ṣàwárí Lefitiku 19:28
3
Lefitiku 19:2
“Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi OLúWA Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.
Ṣàwárí Lefitiku 19:2
4
Lefitiku 19:17
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.
Ṣàwárí Lefitiku 19:17
5
Lefitiku 19:31
“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.
Ṣàwárí Lefitiku 19:31
6
Lefitiku 19:16
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni OLúWA.
Ṣàwárí Lefitiku 19:16
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò