“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá
lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLúWA wí pé:
“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,
èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.
Èmi ó jẹ́ OLúWA wọn;
àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.
Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀
tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLúWA,’
nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí
láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”
ni OLúWA wí.
“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,
èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”