Báyìí ni OLúWA wí:
“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLúWA
Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.