Jer 17:7-8
Jer 17:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀! Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso.
Jer 17:7-8 Yoruba Bible (YCE)
“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò, tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò. Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé, nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini. Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀, nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.
Jer 17:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, tí ó sì fi OLúWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”