1
Deuteronomi 4:29
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Bí ẹ̀yin bá wá OLúWA Ọlọ́run yín láti bẹ̀ ẹ́, ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Deuteronomi 4:29
2
Deuteronomi 4:31
Nítorí pé OLúWA Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:31
3
Deuteronomi 4:24
Torí pé iná ajónirun ni OLúWA Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:24
4
Deuteronomi 4:9
Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:9
5
Deuteronomi 4:39
Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé OLúWA ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:39
6
Deuteronomi 4:7
Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí OLúWA Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkúgbà tí a bá ń ké pè é?
Ṣàwárí Deuteronomi 4:7
7
Deuteronomi 4:30
Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ OLúWA Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:30
8
Deuteronomi 4:2
Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin OLúWA Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.
Ṣàwárí Deuteronomi 4:2
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò