1
Ìṣe àwọn Aposteli 20:35
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 20:35
2
Ìṣe àwọn Aposteli 20:24
Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 20:24
3
Ìṣe àwọn Aposteli 20:28
Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 20:28
4
Ìṣe àwọn Aposteli 20:32
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 20:32
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò