Iṣe Apo 20:35
Iṣe Apo 20:35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ.
Iṣe Apo 20:35 Yoruba Bible (YCE)
Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ”