1
1 Kronika 16:11
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ wá OLúWA àti agbára rẹ̀; E wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Kronika 16:11
2
1 Kronika 16:34
Fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:34
3
1 Kronika 16:8
Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe
Ṣàwárí 1 Kronika 16:8
4
1 Kronika 16:10
Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin OLúWA kí ó yọ̀.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:10
5
1 Kronika 16:12
Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:12
6
1 Kronika 16:9
Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀
Ṣàwárí 1 Kronika 16:9
7
1 Kronika 16:25
Nítorí títóbi ni OLúWA òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:25
8
1 Kronika 16:29
Fún OLúWA ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. Sìn OLúWA nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:29
9
1 Kronika 16:27
Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:27
10
1 Kronika 16:23
Kọrin sí OLúWA gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:23
11
1 Kronika 16:24
Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:24
12
1 Kronika 16:22
“Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni ààmì òróró mi; Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”
Ṣàwárí 1 Kronika 16:22
13
1 Kronika 16:26
Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, ṣùgbọ́n OLúWA dá àwọn ọ̀run.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:26
14
1 Kronika 16:15
Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran
Ṣàwárí 1 Kronika 16:15
15
1 Kronika 16:31
Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “OLúWA jẹ ọba!”
Ṣàwárí 1 Kronika 16:31
16
1 Kronika 16:36
Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé “Àmín,” wọ́n sì “Yin OLúWA.”
Ṣàwárí 1 Kronika 16:36
17
1 Kronika 16:28
Fi fún OLúWA, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún OLúWA.
Ṣàwárí 1 Kronika 16:28
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò