1
ÌWÉ ÒWE 17:17
Yoruba Bible
Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:17
2
ÌWÉ ÒWE 17:22
Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara, ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:22
3
ÌWÉ ÒWE 17:9
Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́, ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:9
4
ÌWÉ ÒWE 17:27
Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:27
5
ÌWÉ ÒWE 17:28
A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n, bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́, olóye ni àwọn eniyan yóo pè é, bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:28
6
ÌWÉ ÒWE 17:1
Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀, ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:1
7
ÌWÉ ÒWE 17:14
Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé, dá a dúró kí ó tó di ńlá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:14
8
ÌWÉ ÒWE 17:15
Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́bi ati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre, OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 17:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò