1
ÌWÉ ÒWE 16:3
Yoruba Bible
Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:3
2
ÌWÉ ÒWE 16:9
Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:9
3
ÌWÉ ÒWE 16:24
Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin, a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:24
4
ÌWÉ ÒWE 16:1
Èrò ọkàn ni ti eniyan ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:1
5
ÌWÉ ÒWE 16:32
Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:32
6
ÌWÉ ÒWE 16:18
Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:18
7
ÌWÉ ÒWE 16:2
Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀, ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:2
8
ÌWÉ ÒWE 16:20
Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn, ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:20
9
ÌWÉ ÒWE 16:8
Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:8
10
ÌWÉ ÒWE 16:25
Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:25
11
ÌWÉ ÒWE 16:28
Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀, ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 16:28
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò