Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé,
“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé,
‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn!
Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí
gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké
ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀.
A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ,
a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán
Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”