Luk 3:21-22
Luk 3:21-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀, Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.
Pín
Kà Luk 3Luk 3:21-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”
Pín
Kà Luk 3Luk 3:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
Pín
Kà Luk 3