1
JẸNẸSISI 14:20
Yoruba Bible
Ìyìn sì ni fún Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ.” Abramu bá fún Mẹlikisẹdẹki ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun tí ó kó bọ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JẸNẸSISI 14:20
2
JẸNẸSISI 14:18-19
Mẹlikisẹdẹki ọba Salẹmu náà mú oúnjẹ ati ọtí waini wá pàdé rẹ̀. Mẹlikisẹdẹki jẹ́ alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Ó súre fún Abramu, ó ní: “Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu.
Ṣàwárí JẸNẸSISI 14:18-19
3
JẸNẸSISI 14:22-23
Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀.
Ṣàwárí JẸNẸSISI 14:22-23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò