Gẹn 14:22-23
Gẹn 14:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye, Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀
Pín
Kà Gẹn 14Gẹn 14:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀.
Pín
Kà Gẹn 14Gẹn 14:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún OLúWA, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’
Pín
Kà Gẹn 14