1
TẸSALONIKA KINNI 5:16-18
Yoruba Bible
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:16-18
2
TẸSALONIKA KINNI 5:23-24
Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn. Ẹni tí ó pè yín yóo ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé olóòótọ́ ni.
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:23-24
3
TẸSALONIKA KINNI 5:15
Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan.
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:15
4
TẸSALONIKA KINNI 5:11
Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín ninu, kí ẹ sì máa fún ara yín ní ìwúrí, bí ẹ ti ń ṣe.
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:11
5
TẸSALONIKA KINNI 5:14
Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan.
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:14
6
TẸSALONIKA KINNI 5:9
Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:9
7
TẸSALONIKA KINNI 5:5
Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn.
Ṣàwárí TẸSALONIKA KINNI 5:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò