Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́, n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae.