I. A. Ọba 9:4-5
I. A. Ọba 9:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́, Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’
I. A. Ọba 9:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi iwọ o ba rìn niwaju mi: bi Dafidi baba rẹ ti rìn, ni otitọ ọkàn, ati ni iduroṣinṣin, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, ti iwọ o si pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́: Nigbana li emi o fi idi itẹ́ ijọba rẹ mulẹ lori Israeli titi lai, bi mo ti ṣe ileri fun Dafidi baba rẹ, wipe, Iwọ kì yio fẹ ọkunrin kan kù lori itẹ́ Israeli.
I. A. Ọba 9:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́, n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae.