Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.