I. A. Ọba 3:6
I. A. Ọba 3:6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi.
I. A. Ọba 3:6 Yoruba Bible (YCE)
Solomoni dá OLUWA lóhùn, ó ní: “O ti fi ìfẹ́ ńlá rẹ, tí kìí yẹ̀ hàn sí Dafidi, baba mi, iranṣẹ rẹ, nítorí pé ó bá ọ lò pẹlu òtítọ́, òdodo ati ọkàn dídúró ṣinṣin. O sì ti fi ìfẹ́ ńlá tí kì í yẹ̀ yìí hàn sí i, o fún un ní ọmọ tí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.
I. A. Ọba 3:6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.