Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Owe 3:7
Dídàgbà Nínú Ìfẹ́
Ọjọ́ 5
Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.
Jesu fẹràn mi
Ọjọ́ Méje
Tí ẹnìkan bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, “Kí nì mo ní láti gbàgbọ láti lè jẹ́ Kristẹni?” Kí nì ó sọ? Olùṣọ́-àgùntàn tó jẹ akọròyìn tẹ́lẹ̀ lo ọ̀rọ̀ orin, “Jésù Fẹ Mi Mo Mọ Bẹ́ẹ̀, Bíbélì L’o Sọ Fún Mi” láti jẹ́ kí ìgbàgbọ yé ọ. Akọ̀wé John S. Dickerson ṣàlàyé àwọn ìgbàgbọ ti Kristẹni àti ìdí tí wọ́n ṣe pàtàkì.
Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀
Ojó Méwàá
Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.