Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 8:36

Ìyípadà-Pátá Kúrò Nínú Afẹ́sódì
Ojo meta
Níìgbàtí ìgbé ayé rẹ bá kúrò ní ìlànà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọ́run, ó fẹ́rẹ̀ dájú wípé wàá ní ìrírí àwọn àtunbọ̀tán tí ó ní ìrora. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóti tiraka pẹ̀lú ìlera wọn, wọ́n pàdánù iṣẹ́, àti àwọn ìbáṣepọ̀, wọ́n bá ara wọn nínú ìmọ̀lára pé wọ́n jìnà sí ọlọ́run nítorí àwọn ìkúndún bárakú. Yálà ìkúndùn bárakú tí ó le bíi oògùn olóró tàbí àwòrán ìwòkúwò tàbí ìkúndùn bárakú tí ó ṣẹ́ pẹ́rẹ́, bíi oúńjẹ tàbí ìdánilárayá, àwọn ìkúndùn bárakú a máa da ètò ayé wa rú. Jẹ́ kí Tony Evans ońkọ̀wé tí ó tàjù fi ọ̀nà òmìnira hàn ọ́.

A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ Rékọjá
Ojọ́ Márùn-ún
Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.