Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Isa 6:8

Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọjọ́ Márùn-ún
Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

Ìpè sí Iṣẹ́ Aṣíwájú tó jẹ́ Ìránṣẹ́
5 Awọn ọjọ
A pè wá sí iṣẹ́ aṣíwájú bíi Jesu. Iṣẹ́ aṣíwájú bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara-ẹni, kìí ṣe ipò, ibi-àfẹ́dé Iṣẹ́ aṣíwájú sì jẹmọ́ ìdarí àwọn ènìyàn Ọlọrun sí ìpinnu Rẹ̀ fún ayé wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́-kíkà ojoojúmọ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ fífẹsẹ̀mulẹ̀ nípa ipò aṣíwájú tó ńránnilétí pé, kí o tó jẹ́ aṣíwájú, o kọ́kọ́ jẹ́ ìránṣẹ́, kí o tó jẹ́ ìránṣẹ́, o kọ́kọ́ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ-Ọlọrun

Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwu
Ọjọ́ Méje
Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

Oswald Chambers: Ìdùnnú - Agbára Nínú Olúwa
Ọgbọ̀n ọjọ́
Sàwárí òye ti Oswald Chambers, olùkọ̀wé Sísa gbogbo ipá fún Gíga jùlọ, nínú ìṣúra èyí òye inú nípa ìdùnnú. Àwon àyọlò ọ̀rọ̀ tún tayọ nínú èkó kíkà kọ̀ọ̀kan láti Chambers nírẹ̀ẹ́pọ̀ pèlú àwon ìbéèrè fún Ijiroro tiré gan. Bí ó se mísí o àti pè o níjà pèlú òyé rè tó rorùn àti òye Bíbèlí, wa a rí ara re n fé láti lo àkókò sí i ni bibá Olórun sòrò.