Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Isa 55:9

Bí A Ti Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Ní Ka Bíbélì
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Lòótọ́, a mọ̀ pé kíka Bíbélì dára, ṣùgbọ́n ó le ṣòro láti mọ ibi tí a ti le bẹ̀rẹ̀. Ní ọjọ́ mẹrin tó ń bọ̀, a ó máa kọ nípa ìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì, bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ ìwà ìwé-kíka ojoojúmọ́, àti bí a ṣe lè lò ní ayé wa ti òní.

Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna Light
Ọjọ́ Méje
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ

Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú Wúwo
Ọjọ́ Méje
Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.

Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín Ìdánwò
Ọjọ́ Méje
A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.

Fun Eto Ayọ Ṣaaju Rẹ: Ẹrọ Ọjọ ajinde Kristi
Ọjọ́ mẹ́jọ
Ọsẹ ikẹhin ninu igbesi aye Jesu kii ṣe ọsẹ lasan. O jẹ akoko ti awọn ohun elo ti o dara bittersweet, fifun lavish, awọn iwa ika ati awọn adura ti o gbọn ọrun. Ni iriri ni ọsẹ yii, lati Palm Sunday si Ajinde iyanu, bi a ti ka nipasẹ akọọlẹ Bibeli papọ. A yoo ni idunnu pẹlu awọn eniyan lori awọn opopona Jerusalẹmu, kigbe ni ibinu ni Juda ati awọn ọmọ-ogun Romu, kigbe pẹlu awọn obinrin ni Agbelebu, ati ṣe ayẹyẹ bi owurọ owurọ Ọjọ ajinde Kristi!

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ojo Méjìlá
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!

Oswald Chambers: Ìdùnnú - Agbára Nínú Olúwa
Ọgbọ̀n ọjọ́
Sàwárí òye ti Oswald Chambers, olùkọ̀wé Sísa gbogbo ipá fún Gíga jùlọ, nínú ìṣúra èyí òye inú nípa ìdùnnú. Àwon àyọlò ọ̀rọ̀ tún tayọ nínú èkó kíkà kọ̀ọ̀kan láti Chambers nírẹ̀ẹ́pọ̀ pèlú àwon ìbéèrè fún Ijiroro tiré gan. Bí ó se mísí o àti pè o níjà pèlú òyé rè tó rorùn àti òye Bíbèlí, wa a rí ara re n fé láti lo àkókò sí i ni bibá Olórun sòrò.