Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Efe 6:18
Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?
Ọjọ marun
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ìhámọ́ra Ọlọ́run
Ọjọ marun
Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.
Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò Kérésìmesì
Ọjọ 5
Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.
Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́
Ọjọ́ mẹ́fà
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.
Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun wa
Ọjọ́ Méje
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.
Ìgbàgbọ́
Ojo Méjìlá
Se rírí ni gbígbàgbọ rírí? Tàbí gbígbàgbọ ni rírí? Àwon ibeere ti ígbàgbọ niyen. Ètò yi pèsè ẹ́kọ̀ọ́ to jíjinlẹ̀ ti ígbàgbọ làtí àwon ìtàn ti Májẹ̀mú láéláé ti àwọn èèyàn òtító tiwon se àṣefihàn ígboyà ígbàgbọ nínú Ipò aiseéṣe ti Jésù’ kẹ́kọ̀ọ́ lori ékò náá. Nípasẹ̀ kíkà ètò yií, wani ìṣírí láti mu ìbáṣepò rè pélù Olórun jinlẹ̀ si ati láti túbọ̀ di ọmọlẹ́yìn onígbàgbọ ti Jésù.