Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Efe 6:18

Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?
Ọjọ marun
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.

Ìhámọ́ra Ọlọ́run
Ọjọ marun
Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.

Bí ìgbé ayé ṣe yí padà: Ní àkókò Kérésìmesì
Ọjọ 5
Nínú gbogbo ìgbòkègbodò ọdún, ó ṣeéṣe kí a má kíyèsára ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn bíbọ̀ Oluwa yí a ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlérí tí ìbí Rẹ̀ mú wá sí ìmúṣẹ nípa bí a ṣe bí Jésù àti ìrètí tí a ní fún ọjọ́ iwájú. Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ sí í nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, a ó ṣe àwárí bí a ṣe lè máa gbé ní àkókò ìsinmi ọdún pẹ̀lú ìrètí, ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti àlàáfíà.

Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́
Ọjọ́ mẹ́fà
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.

Jésù: àsíá Ìṣẹ́gun wa
Ọjọ́ Méje
Nígbà tí a bá ń ṣe ayẹyẹ ajinde, à ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ nínú ìtàn. Nípa ikú àti ajinde Jésù', ó borí agbára ẹ̀ṣẹ̀ àti isà òkú títí láí, àti gbogbo ohun àbájáde wọn, ó sì yàn láti pín ìṣẹ́gun náà pẹ̀lú wa. Ní ọ̀sẹ̀ ayẹyẹ yii, jẹ́ kí á wọ inú díẹ̀ nínú àwọn odi agbára tí ó ṣẹ́gun, ṣe àṣàrò lóríi ìjà tí ó jà fún wa, kí o sì yìín gẹ́gẹ́bíi àsíá ìṣẹ́gun wa.