Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Kol 4:3
Àwọn Ará Kólósè
4 Awọn ọjọ
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
Àdúrà
Ọjọ́ Mọ́kànlé-Lógún
Kọ́ bí ó ṣe dára jùlọ láti gbàdúrà, láti inú ádùrá àwọn olódodo àti láti àwọn ọ̀rọ̀ Jésù fún rara Rẹ̀. Wá ìwúrí láti máa mú àwọn ìbéèrè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run l'ójoojúmọ́, pẹ̀lú ìtẹramọ́ṣẹ́ àti sùúrù. Ṣ'àwárí àwọn àpẹẹrẹ ádùrá òfo, òdodo ti ara ẹni, èyí tí ó ṣe déédé sí àwọn ádùrá mímọ́ ti àwọn tí ó ní ọkàn mímọ́. Gbàdúrà nígbà gbogbo.