Gẹn Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìtumọ̀ Gẹnẹsisi ni “Ìpìlẹ̀” tabi “Ìṣẹ̀dálẹ̀.” Inú ìwé Jẹnẹsisi ni ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé wà; bí a ti ṣẹ̀dá ọmọ eniyan, ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati bí ìnira ṣe bẹ̀rẹ̀ láyé, ati ìhà tí Ọlọrun kọ sí eniyan. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé Jẹnẹsisi sí:
1) Orí 1-11 Ìtàn nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ìtàn ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan. Bákan náà, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ a óo rí kà nípa Adamu ati Efa, Kaini ati Abeli, Noa ati ìkún omi, ati nípa ilé ìṣọ́ Babiloni.
2) Orí 12-50: Ìtàn àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli. Abrahamu ni ẹni àkọ́kọ́, ó jẹ́ olókìkí eniyan nípa ẹ̀mí igbagbọ tí ó ní, ati ìgbọràn sí Ọlọrun. Ìtàn ọmọ rẹ̀, Isaaki, ni ó tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà ni ti ọmọ ọmọ rẹ̀, Jakọbu, (tí ó tún ń jẹ́ Israẹli), ati ti àwọn ọmọ Jakọbu mejeejila, àwọn ni wọ́n pilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Ní pataki, ìtàn Josẹfu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli jẹyọ ati ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe okùnfà bí Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ẹbí wọn ṣe di èrò Ijipti, (ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe àtìpó).
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé yìí sọ ọpọlọpọ ìtàn nípa eniyan, sibẹ ohun tí Ọlọrun ṣe ni ó pilẹ̀ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ kókó pataki. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, a rí ẹ̀rí ìdánilójú pé Ọlọrun ni ó dá ayé, ní ìkẹyìn, Ọlọrun ṣèlérí pé òun yóo máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn eniyan òun. Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ìwé náà, Ọlọrun ni ẹ̀dá ìtàn tí ó súyọ jùlọ, òun ni onídàájọ́, a sì máa fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, a máa darí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́, bákan náà ni ó máa ń ṣàkóso ìgbésí ayé wọn. A kọ ìwé àtayébáyé yìí láti ṣe àgbékalẹ̀ ìtàn nípa igbagbọ àwọn eniyan kan ati pé kí iná irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ baà lè máa jó àjóròkè sí i.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ti ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan 1:1—2:25
Ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati ìjìyà 3:1-24
Ìtàn láti orí Adamu títí dé ti Noa 4:1—5:32
Noa ati ìkún omi 6:1—10:32
Ilé ìṣọ́ Babilonii 11:1-9
Ìtàn láti orí Ṣemu títí dé ti Abramu 11:10-32
Àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli: Abrahamu, Isaaki, Jakọbu 12:1—35:29
Àwọn arọmọdọmọ Esau 36:1-43
Josẹfu ati àwọn arakunrin rẹ̀ 37:1—45:28
Àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ Ijipti 46:1—50:26
Voafantina amin'izao fotoana izao:
Gẹn Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Asongadina
Hizara
Dika mitovy
Tianao hovoatahiry amin'ireo fitaovana ampiasainao rehetra ve ireo nasongadina? Hisoratra na Hiditra
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.